Yemi my lover biography
Yemi my lover biography
Yemi my lover biography book...
Yemi Ayebo, Yemi My Lover: Ìdí rèé tí orin kíkọ fi máa ń pò nínú sinimá mi...
Bi ẹ ba jẹ ẹni to n fi ọkan ba ere sinima lorileede Naijiria bọ daadaa, kete ti wọn ba ti darukọ Yemi My Lover, ko ni ṣe yin ni kayeefi.
Gbajugbaja elere sinima yii, Yemi Ayebo ni BBC Yoruba gba lalejo lori eto wa loju opo Facebook.
Ninu ifọrọwero naa ti pupọ awọn ololufẹ rẹ ti darapọ mọ wa Yemi My Lover tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa awọn nkankan.
Lara ohun to sọ fawọn ololufẹ rẹ ni ipa to ko ninu ere sinima Naijiria paapaa julọ nipa ṣiṣe atọna fawọn elere sinima to ti wa gun oke agba loni.
O sọ pe Afees Ọwọ ti o wa di ilumọọka loni jẹ ọkan lara awọn to kọṣẹ sinima lọdọ ohun.
Koda o ni orukọ inagijẹ rẹ''Ọwọ'' to n jẹ ''emi ni mo fun un.''
Sinima nipa igbe aye Yemi My Lover n bọ
Ọmọ bibi ikarẹ ni Ilu Ondo,Yemi Ayebo wa lara awọn to kọkọ tan irawọ ere sinima agbelewo lede Yoruba pèlu awọn sinima bi Yemi My Lover, Joke Onibudo ati Ọdẹ Aperin.